Oriki Olomu-Aperan
Omo Olomu Aperan
Omo oloro alagogo ajilu
Omo onilu bambatimba
Omo onilu ti won kii fi awo ekun se
Afi awo eketepe eti erin
Omu mosi o ba iroko pobi
Igi tie yin batan ni igbe o kere
Igi olorin ni ibatan
Omu mosi omo apewo baruko
Mosi lode ore
Irele awusi l'omu
Agan yo lolo jana l'omu
Ogberi ko mo pe owo agan soro
Omo lolhun titimbiri
Bi ewure ba sonu l'omu mosi ile
Moni e ma fi lo mi
Baba tani ise egeb gberan gberan
Bi aguntan bolojo ba sonu l'omu ni ile oloro
Moni e ma fi lomi rara
Baba tani ise egbe gberan gberan
Ani bi adie okoko ba sonu l'omu ni ile oloro
Moni ki e mafilomi, rara se
Baba tani ise egbe gbeye gbeye
Orii bi omobinrin kan rogbodo
To ledan lorun
To tadi reke reke
Ba sonu l'omu ni ile oloro
Moni emase ran elese ko le ya
Eniti o ba gun esin ni ki eran si mi
Omo naa ko ku rara
Omo naa ko sokunrun
O nbe ni ile baba awa
Awa omo aropon nla jomitoro esin
Eniti o gbe arewa obinrin ko fewo
Eniti o gbe eran lo digara
Sebi agbe ewure lodi ikan
Aji agutan gbe lojale l'omu
Ibosi agabdie ni iagara nke
Omo Olohun titimbiri
Amo lojo tie sin kan bolojo
Ba sonu l'omu, ni ile oloro
Ki e mura sare tete de be
Awon ni omo aropon nla jomitoto esin
|
Nigbati omoitoto esin dele l'omu ni ile oloro
Won ni ki gbogbo omosu ile
Wa maa la omitoro esin
Omuse, omo gbontikan
Ogidigbo onilu so ilujo
Alukosos ni ji oba loju orun
Won lu iyangba mio gbodo pa ese da
Ikoko kuduru ni won lu l'omu ni ile oloro
Ni mo gbewo ijo gangan
Ti mo gborin ga
Osi omu, ogogi ara iraye
Omo a mu orugbo sodun
Bi igba iyan se ogun
Ti eru oka se ogbon
Ko to ogigi ara iraye pin ni gbo Areko
Okanlelegberun eko, omo sisan loju ogun
Wiwa mu logbokanla iyoku
Omo aropon nla jomitoro esin
Osi omu, bi a bimi lorokan maa dagba lee
Ilu mi erigi omu
Ija abosi ni won ko l'omu ni ile oloro
Omuse omo oye-ni-si
Omo egungun ti fori egungun gbagi labara
Aa ni dagun l'omu aani jebi ogun
Ani fopo eniyan dagun l'omuye
Olomu, Aperan, omo oro tin pani lesin
Asingba modun dona t'omu
Agogo nla ti nsunkun para oko
Bi won oo banija l'omu
Wo a ni ko wa ponti areko
Elegbaagun, moni kole ponti areko
Elgbeaagbon dona o dehin
Ologota ni bobo daran tan
O pada wale o wa win owo
Akoloro oja ojomu
Omu mosi a mu orugbo sodun
Nigbati mo de ehinkule olomu lojo ojo si
Ni be ni won gbe fi iyan fa odi kara
Iyan o lowo; iyan o lese
Iyan ngugi l areko
Omo boo jotun tan ofi ewu de mi
|
| Personality of the Month |

Bishop David Oyedepo
Host of Omu-Aran Day '08 |
| Advertise |
|
|
|